Èdè Lárúbáwá

Ède Lárúbáwá tabi ede Araabu Ara èdè Sẹ̀mítíìkì ni èdè Àrábíìkì (Arabic (Èdè Lárúbááwá)). Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíọ̀nù lọ́nà igba gẹ́gẹ́ bí èdè abíníbí ní àríwá Aáfíríkà àti ìlà-oòrùn-gúsù Eésíà (Asia). Àìmoye ènìyàn tí a kò lè fi ojú da iye wọn ni ó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì, ìyẹn èdè àkọ́kún-tẹni ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Mùsùlùmú ti gbilẹ̀. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní pàtàkì ní ilẹ̀ faransé náà máa ń sọ èdè yìí. Ibi tí àwọn tí ó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí ju ni Algeria, Egypt, Iraq, Morocco, Saudi Arabia, Sudan, Syria, Tunisia àti Yeman. Àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ kan wà tí ó jẹ́ ti apá ìwọ̀-oòrùn tí àwọn kan sì jẹ́ ti ìlà-oòrùn. Èdè tí a fi kọ kọ̀ráànù sílẹ̀ ni a ń pè ní ‘Classical’ tàbí ‘Literary Arabic’. Èdè mímọ́ ni gbogbo mùsùlùmú àgbáyé tí ó tó ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní àgbáyé (1, 100 million) nínú ètò ìkànìyàn 1995 ni ó mọ èdè ‘Classical Arabic’ yìí. Olórí ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá wà tí ó sún mọ́ èyí tí wọ́n fi kọ Kọ̀ráànù. Eléyìí ni wọ́n fi ń kọ nǹkan sílẹ̀. Òun náà ni wọ́n sì máa ń lo dípò àwọn ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ẹ̀ka-èdè lárúbáwá yìí ni wọ́n kò gbọ́ ara wọn ní àgbóyé. Méjìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Lárúbááwá. Apé ọ̀tún ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé wá sí apá òsù Yàtọ̀ sí álúfásẹ́ẹ̀tì ti Rómáànù, ti Lárúbáwá ni àwọn ènìyàn tún ń lò jù ní àgbáyé. A ti rí àpẹẹrẹ pé láti nǹkan bíi sẹ́ńtérì kẹ́ta ni a ti ń fi èdè Lárúbáwá kọ nǹkan sílẹ̀. Nígbà tí ẹ̀sìn mu`sùlùmí dé ní sẹ́ńtúrì kéje ni òkọsílẹ̀ èdè yìí wá gbájúgbajà. Wọ́n tún wá jí sí ètò ìkọsílè èdè yìí gan-an ní séńtúrì kọ́kàndínlógún nígbà tí ìkọsílẹ̀ èdè yìí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìwọ̀-oòrùn Úróòpù. Ní pele-ń-pele ni èdè yìí pín sí (ìyẹn ni pé eléyìí tí olówó ń sọ lè yàtọ̀ sí ti tálíkà tàbí kí ó jẹ́ pé eléyìí tí obìnrin ń lò lè yàtọ̀ sí ti ọkùnrin).

Èdè Lárúbáwá
العربية al-ʿarabīyah
Arabic albayancalligraphy
Ìpè /alˌʕaraˈbiːja/
Sísọ ní Primarily in the Arab states of the Middle East and North Africa;
liturgical language of Islam.
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀ Approx. 280 million native speakers[1] and 250 million non-native speakers[2]
Èdè ìbátan
Afro-Asiatic
 • Semitic
  • West Semitic
   • Central Semitic
    • Arabic
     • Èdè Lárúbáwá
Sístẹ́mù ìkọ Arabic alphabet, Syriac alphabet (Garshuni), Bengali script [1] [2]
Lílò bíi oníbiṣẹ́
Èdè oníbiṣẹ́ ní Official language of 25 countries, the third most after English and French[3]
Àkóso lọ́wọ́

Algeria: Supreme Council of the Arabic language in Algeria
Egypt: Academy of the Arabic Language in Cairo
Iraq: Iraqi Academy of Sciences
Jordan: Jordan Academy of Arabic
Libya: Academy of the Arabic Language in Jamahiriya
Morocco: Academy of the Arabic Language in Rabat
Sudan: Academy of the Arabic Language in Khartum
Syria: Arab Academy of Damascus (the oldest)

Tunisia: Beit Al-Hikma Foundation
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-1 ar
ISO 639-2 ara
ISO 639-3 ara – Arabic (generic)
(see varieties of Arabic for the individual codes)
[[File:
Map of Majority and Minority Arabic Speakers

Map of the Arabic-speaking world.
Green: Majority Arabic Speakers.
Light Green: Minority Arabic Speakers.|300px]]

Awon itokasi

 1. Procházka, 2006.
 2. Ethnologue (1999)
 3. Wright, 2001, p. 492.
Boko Haram

Bòkó Àráámùù, tí wọ́n pe ara wọn

ní Wilāyat Gharb Ifrīqīyyah (èdè lárúbáwá: الولاية الإسلامية غرب أفريقيا‎‎, (Islamic State West Africa Province, ISWAP), àti: Jamā'at Ahl as-Sunnah lid-Da'wah wa'l-Jihād (èdè lárúbáwá: جماعة أهل السنة للدعوة والجهاد‎‎, "Ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn Sunnah fún ìwàásù àti Jihad"), jẹ́ ẹgbẹ́ ìmàle tí ó wà ní àríwá-ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó tún ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè Chad, Niger àti àríwá Cameroon. Olórí ẹgbẹ́ yìí ní Abubakar Shekau. Ẹgbẹ́ yìí ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú al-Qaeda, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kẹtà ọdún 2015, wọ́n ṣe ìkéde ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn pẹ̀lú Islamic State of Iraq and the Levant (ISIL). Lati ìgbà tí ìdojú ìjà kọ ìjọba yìí tí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2009, ẹgbẹ̀rú lọ́na ogún ènìyàn ni wọ́n ti pa, tí wọ́n sí sọ ènìyàn mílíọ́nù méjì àti ọgọ́rún mẹ́ta di aláìnílé tí wọ́n sì ṣe ipò kínín nínú àwọn ẹgbẹ́ jàndùkú tí ó wà ní gbogbo àgbàyé, àwọn Global Terrorism Index ni wọ́n ṣe àkójọ yìí ní ọdún 2015.

Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2002, ìpánle Boko Haram peléke tí ó sì ṣe okùnfà ikú olórí wọn ní oṣù keje ọdún 2009. Wọ́n tún yọjú àìmọ̀tẹ́lẹ̀, lẹ́yín ìfipá já ọgbà ẹ̀wọn ní Oṣù kẹsán ọdún 2010, bẹ́ẹ̀ni ìdojúìjà àwọn ènìyàn ń peléke síi, lakọ́kọ, wọ́n ń dojú ìjà kọ àwọn tí kò lágbáraa, bẹ́ẹ̀ ni wàhálà yìí pọ̀ síi ní ọdún 2011 tí ó fi di àwọn ìfàdó olóropànìyàn paraẹni tí ó ṣelẹ̀ ní ọgbà olọ́pa àti United Nation ní Abuja. Ìgbéṣẹ̀ ìjọba àpapọ̀ lati ṣàyipada sí àwọn ijọba ìpínlẹ̀ tí ó wà ní àríwá ìlà-oòrùn Nàìjíríà ní ọdún 2012, tí ó tún ṭ̀síwájú síi ní ọdún tó tẹ̀le fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlòkúlò àwọn ológun ti ààbò àti ìdojú ìjà kọ àwọn ènìyan lọ́wọ àwọn tí ó ń dojú ìjà kọ ìjọba.

Nínú àwọn ènìyàn mílíọ́nù méjì àti ọgọ́rún mẹ́ta tí wọ́n ti sọ di aláìnílé lasti Oṣù karún ọdún 2013, ókéré jù, bíi ènìyàn 250,000 ti fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ sí Cameroon, Chad tàbí Niger. Boko Haram pa àwọn ènìyàn tí ó ju 6,600 lọ ní Ọdún 2014. Ẹgbẹ́ yìí fipá kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ àti ìfipá kó akẹ́kọ́ igba lé mẹ́rìndínlọ́gọrin kúrò ní Chibok ní Oṣù kẹrin Ọdún 2014. Ìwàìbàjẹ́ nínú àwọn òṣìṣẹ́ ààbò àti àwọn ajàfẹ́tọ àwọn ènìyàn jẹ́ kí ìgbìyànjú àti bẹ́gilé àìní ìsinmi yí ṣòro.

Ní bi àárín ọdún 2014, gba ìletò tí ó yí ilé wọn ká ní ìpínlẹ̀ Borno, tí a ṣírò sí bí 50,000 square kilometres (20,000 sq mi) ní Oṣù kínín Ọdún 2015, ṣùgbọ́n wọn kò rí ìpínlẹ̀ Maiduguri kó, ní ibi tí ẹgbẹ́ yìí ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Ní oṣù kẹsán ọdún, 2015, olùdarí ìròyìn fún olúilé iṣẹ́ ológun tí Nàìjíríà sọọ́ di mímọ̀ pé wọ́n ti ba gbogbo abà Boko Haram jẹ́.

Sheik Adam Abdullah Al-Ilory

Seik Adam Abdullah Al-Ilory ni wọ́n bí ní ọdún (1917-1992), sí ìdílé Ṣéù Abdul Baqi Al-Ilory. Ó jẹ́ àṣáájú onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú èsìn Islam ní orílẹ̀ èdè Benin-Nàìjíríà.

Ó jẹ́ ẹni tí ó tẹ̀lé ìlànà Imam Maliki, tí ó sì jẹ́ òǹkọ̀wé ìmọ̀ oríṣiríṣi nínú èdè Lárúbáwá (Arabic Author). Ó tún jẹ́ oní Súfi ní ìlànà Qadiriyya. Ó dá ilé ẹ̀kọ́ Markhazl-Uluum tí ó wà ní ìlú Agége, agbègbè kéréje kan ní ìpínlẹ̀ Èkó , ní ọdún 1945. Ilé ẹ̀kọ́ náà ní ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ kéú àti Kùránì tí tàn kálẹ̀ láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tó fí wọ Benin, àti gbogbo ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ adúláwọ̀ pátá

Èdè Árámáìkì

Èdè Árámáìkì je ara èdè Sèmítíìkì (Semitic). Àwon tí ó ń so èdè yìí tó egbèrún lónà igba ní Ìráànù (Iran) àti Ìráàkì (Iraq) pèlú òpòlopò àwon mìíràn tí wón tún ń so ó ní Ààrin gbùngbùn ìlà-òòrùn àgbáyé (Middle tast). Láti séńtúrì kefà ni wón ti ń fi Árámáìkì àtijó (Classical Aramaic) ko nnkan sílè ní Ààrin gbingbein ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East). Hébéérù ni ó wá gba ipò rè gégé bí èdè tí àwon júù ń so.

Èka-èdè ìwò-oòrùn èdè yìí (Western dialect) ni èdè tí Jéésù Kristì àti àwon omo èyìn rè ń so. Èka-èdè kán tí ó wá láti ara èka-èdè yìí ni wón sì ń so ní àwon abúlé kan ní ilè Síríà àti Lébánóònù.

Ní nnkan bíi séńtúrì kéje ni èdè Lárúbáwá gba ipò èdè Árámáìkì. Èka-èdè apá ìwo-oòrùn èdè yìí tí a ń pè ní Síríàkì (Syricac) ni àwon ìjo Àgùdà ará fíríàkì (Syriac Catholic) ń lò.

Álúfábéètì méjìlélógún ni èdè yìí ní. Èdè yìí sì se pàtàkì nítorí pé láti ara rè ni Hébéérù, Lárúbáwá àti àwon èdè mìíràn ti dìde.

Àwọn èdè míràn

This page is based on a Wikipedia article written by authors (here).
Text is available under the CC BY-SA 3.0 license; additional terms may apply.
Images, videos and audio are available under their respective licenses.